Ìfihàn 12:15-18 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ni ejò yìí bá tú omi jáde lẹ́nu bí odò, kí omi lè gbé obinrin náà lọ.

16. Ṣugbọn ilẹ̀ ran obinrin náà lọ́wọ́. Ilẹ̀ lanu, ó fa omi tí Ẹranko Ewèlè náà tu jáde lẹ́nu mu.

17. Inú wá bí Ẹranko Ewèlè yìí sí obinrin náà. Ó wá lọ gbógun ti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń pa àṣẹ Ọlọrun mọ́, tí wọn ń jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu.

18. Ó dúró lórí iyanrìn etí òkun.

Ìfihàn 12