43. Ṣebí àtíbàbà Moleki ni ẹ gbé rù,ati ìràwọ̀ Refani oriṣa yín,àwọn ère tí ẹ ṣe láti máa foríbalẹ̀ fún?N óo le yín lọ sí ìgbèkùn, ẹ óo kọjá Babiloni.’
44. “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí kan ní aṣálẹ̀. Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀, ó sì pàṣẹ fún un pé kí ó ṣe àgọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí òun ti fihàn án tẹ́lẹ̀.
45. Àwọn baba wa tí wọ́n tẹ̀lé Joṣua gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun lé kúrò níwájú wọn, lẹ́yìn náà wọ́n gbé àgọ́ náà wá. Àgọ́ yìí sì wà pẹlu wa títí di àkókò Dafidi.
46. Dafidi bá ojurere Ọlọrun pàdé; ó wá bèèrè pé kí Ọlọrun jẹ́ kí òun kọ́ ilé fún òun, Ọlọrun Jakọbu.
47. Ṣugbọn Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un.
48. “Bẹ́ẹ̀ ni Ọba tí ó ga jùlọ kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́. Gẹ́gẹ́ bí wolii nì ti sọ:
49. ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni tìmùtìmù ìtìsẹ̀ mi.Irú ilé wo ni ẹ̀ báà kọ́ fún mi?Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí.Níbo ni ẹ̀ báà palẹ̀ mọ́ fún mi pé kí n ti máa sinmi?
50. Ṣebí èmi ni mo fọwọ́ mi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi?’
51. “Ẹ̀yin olóríkunkun, ọlọ́kàn líle, elétí dídi wọnyi! Nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń tako Ẹ̀mí Mímọ́. Bí àwọn baba yín ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà rí.