Ìṣe Àwọn Aposteli 3:4-7 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Peteru ati Johanu tẹjú mọ́ ọn, Peteru ní, “Wò wá!”

5. Ọkunrin náà bá ń wò wọ́n, ó ń retí pé wọn yóo fún òun ní nǹkan.

6. Peteru bá sọ fún un pé, “N kò ní fadaka tabi wúrà, ṣugbọn n óo fún ọ ní ohun tí mo ní. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasarẹti, máa rìn.”

7. Ó bá fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó gbé e dìde. Lẹsẹkẹsẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ọrùn-ẹsẹ̀ rẹ̀ bá mókun.

Ìṣe Àwọn Aposteli 3