23. Ọ̀gágun náà bá pe meji ninu àwọn balogun ọ̀rún tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó ní, “Ẹ lọ mú igba ọmọ-ogun ati aadọrin ẹlẹ́ṣin ati igba ọmọ-ogun tí ó ní ọ̀kọ̀. Ẹ óo lọ sí Kesaria. Kí ẹ múra láti lọ ní agogo mẹsan-an alẹ́.
24. Ẹ tọ́jú àwọn ẹṣin tí Paulu yóo gùn, kí ẹ sìn ín dé ọ̀dọ̀ Fẹliksi gomina ní alaafia.”
25. Ó wá kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́. Ìwé náà lọ báyìí:
26. “Gomina ọlọ́lá jùlọ, Fẹliksi, èmi Kilaudiu Lisia ki yín.
27. Àwọn Juu mú ọkunrin yìí, wọ́n fẹ́ pa á. Mo gbà á lọ́wọ́ wọn pẹlu àwọn ọmọ-ogun mi nítorí mo gbọ́ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni.
28. Mo fẹ́ mọ ìdí tí wọ́n ṣe fi ẹ̀sùn kàn án. Mo bá mú un lọ sí iwájú ìgbìmọ̀ wọn.
29. Mo rí i pé ẹ̀sùn tí wọ́n ní jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ òfin wọn; kò ṣe ohunkohun tí a lè fi sọ pé kí á pa á tabi kí á jù ú sí ẹ̀wọ̀n.
30. Nígbà tí ìròyìn kàn mí pé àwọn kan láàrin àwọn Juu ti dìtẹ̀ sí ọkunrin yìí, mo bá fi í ranṣẹ si yín. Mo ti sọ fún àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án pé kí wọ́n wá sọ ohun tí wọ́n ní sí i níwájú yín.”
31. Àwọn ọmọ-ogun ṣe bí a ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n mú Paulu lóru lọ sí ìlú Antipatiri.