Ìṣe Àwọn Aposteli 20:13-20 BIBELI MIMỌ (BM)

13. A bọ́ siwaju, a wọkọ̀ ojú omi lọ sí Asọsi. Níbẹ̀ ni a lérò pé Paulu yóo ti wá bá wa tí òun náà yóo sì wọkọ̀. Òun ló ṣe ètò bẹ́ẹ̀ nítorí ó fẹ́ fẹsẹ̀ rìn dé ibẹ̀.

14. Nígbà tí ó bá wa ní Asọsi, ó wọnú ọkọ̀ wa, a bá lọ sí Mitilene.

15. Ní ọjọ́ keji a kúrò níbẹ̀, a dé òdìkejì erékùṣù Kiosi. Ní ọjọ́ kẹta a dé Samosi. Ní ọjọ́ kẹrin a dé Miletu.

16. Nítorí Paulu ti pinnu láti wọkọ̀ kọjá Efesu, kí ó má baà pẹ́ pupọ ní Esia, nítorí ó ń dàníyàn pé bí ó bá ṣeéṣe, òun fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Pẹntikọsti ní Jerusalẹmu.

17. Láti Miletu, Paulu ranṣẹ sí Efesu kí wọ́n lọ pe àwọn alàgbà ìjọ wá.

18. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ bí mo ti lo gbogbo àkókò mi láàrin yín láti ìgbà tí mo ti kọ́kọ́ dé ilẹ̀ Esia.

19. Ẹ mọ̀ bí mo ti fi ìrẹ̀lẹ̀ ati omi ojú sin Oluwa ní ọ̀nà gbogbo ninu àwọn ìṣòro tí mo fara dà nítorí ọ̀tẹ̀ tí àwọn Juu dì sí mi.

20. Ẹ mọ̀ pé n kò dánu dúró láti sọ ohunkohun fun yín tí yóo ṣe yín ní anfaani; mò ń kọ yín ní gbangba ati ninu ilé yín.

Ìṣe Àwọn Aposteli 20