Ìṣe Àwọn Aposteli 17:32-34 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé òkú jinde, àwọn kan ń ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn mìíràn ní, “A tún fẹ́ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí nígbà mìíràn.”

33. Paulu bá jáde kúrò láàrin wọn.

34. Àwọn kan ninu wọn bá fara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́. Ọ̀kan ninu wọn ni Dionisu, adájọ́ ní kóòtù Òkè Areopagu, ati obinrin kan tí ń jẹ́ Damarisi ati àwọn ẹlòmíràn pẹlu wọn.

Ìṣe Àwọn Aposteli 17