Ìṣe Àwọn Aposteli 13:31-42 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni ó fi ara hàn fún àwọn tí wọ́n bá a wá sí Jerusalẹmu láti Galili. Àwọn ni ẹlẹ́rìí fún gbogbo eniyan pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí.

32-33. A wá mú ìyìn rere wá fun yín pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa ti ṣẹ, fún àwọn ọmọ wa, nígbà tí ó jí Jesu dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Orin Dafidi keji pé,‘Ọmọ mi ni ọ́, lónìí yìí ni mo bí ọ.’

34. Ní ti pé ó jí i dìde kúrò ninu òkú, tí kò pada sí ipò ìdíbàjẹ́ mọ́, ohun tí ó sọ ni pé,‘Èmi yóo fun yín ní ohun tí mo bá Dafidi pinnu.’

35. Bẹ́ẹ̀ ni ó tún sọ níbòmíràn pé,‘O kò ní jẹ́ kí Ẹni ọ̀wọ̀ rẹ mọ ìdíbàjẹ́.’

36. Nítorí nígbà tí Dafidi ti sin ìran tirẹ̀ tán gẹ́gẹ́ bí ète Ọlọrun, ó sun oorun ikú, ó lọ bá àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ rà nílẹ̀.

37. Ṣugbọn ẹni tí Ọlọrun jí dìde kò ní ìrírí ìdíbàjẹ́.

38-39. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kí ó hàn si yín pé nítorí ẹni yìí ni a ṣe ń waasu ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹni yìí ni a fi dá gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ láre, àwọn tí Òfin Mose kò lè dá láre.

40. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a kọ sílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii má baà dé ba yín:

41. ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ó yà yín lẹ́nu, kí ẹ sì parun!Nítorí n óo ṣe iṣẹ́ kan ní àkókò yín,tí ẹ kò ní gbàgbọ́ bí ẹnìkan bá ròyìn rẹ̀ fun yín.’ ”

42. Bí Paulu ati Banaba ti ń jáde lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan ń bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n tún pada wá bá wọn sọ irú ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀sẹ̀ tí ó ń bọ̀.

Ìṣe Àwọn Aposteli 13