Ìṣe Àwọn Aposteli 13:11-15 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ọwọ́ Oluwa tẹ̀ ọ́ nisinsinyii. Ojú rẹ yóo fọ́, o kò ní lè rí oòrùn fún ìgbà kan!”Lójú kan náà, ìkùukùu dúdú dà bò ó. Ó bá ń tá ràrà, ó ń wá ẹni tí yóo fà á lọ́wọ́ kiri.

12. Nígbà tí gomina rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó gbàgbọ́; nítorí pé ẹ̀kọ́ nípa Oluwa yà á lẹ́nu.

13. Nígbà tí Paulu ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kúrò ní Pafọsi, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí ìlú Pega ní ilẹ̀ Pamfilia. Johanu fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀, ó pada lọ sí Jerusalẹmu.

14. Wọ́n la ilẹ̀ náà kọjá láti Pega títí wọ́n fi dé ìlú Antioku lẹ́bàá ilẹ̀ Pisidia. Wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu ní Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n bá jókòó.

15. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ka Ìwé Mímọ́, láti inú Ìwé Òfin Mose ati Ìwé àwọn wolii, àwọn olóyè ilé ìpàdé àwọn Juu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin arakunrin, bí ẹ bá ní ọ̀rọ̀ ìyànjú fún àwọn eniyan, ẹ sọ ọ́.”

Ìṣe Àwọn Aposteli 13