1. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ má yọ̀, ẹ sì má dá ara yín ninu dùn, bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nítorí ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, ẹ ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ sọ́dọ̀ oriṣa. Inú yín ń dùn sí owó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ibi ìpakà yín.
2. Ọkà ibi ìpakà yín ati ọtí ibi ìpọntí yín kò ní to yín, kò sì ní sí waini tuntun mọ́.