1. OLUWA ní: “Ẹ ti fèrè bọnu, nítorí ẹyẹ igún wà lórí ilé mi, nítorí pé wọ́n ti yẹ àdéhùn tí mo bá wọn ṣe, wọ́n sì ti rú òfin mi.
2. Wọ́n ń ké pè mí, wọ́n ń wí pé, ‘Ọlọrun wa, àwa ọmọ Israẹli mọ̀ ọ́.’
3. Israẹli ti kọ ohun rere sílẹ̀; nítorí náà, àwọn ọ̀tá yóo máa lépa wọn.
4. “Wọ́n ń fi ọba jẹ, láìsí àṣẹ mi. Wọ́n ń yan àwọn aláṣẹ, ṣugbọn n kò mọ̀ nípa rẹ̀. Wọ́n ń fi fadaka ati wúrà wọn yá ère fún ìparun ara wọn.