Hosia 3:4-5 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo wà fún ọjọ́ gbọọrọ láìní ọba tabi olórí láìsí ẹbọ tabi ère, láìsí aṣọ efodu tabi ère terafimu.

5. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo pada tọ OLUWA Ọlọrun wọn, ati Dafidi, ọba wọn lọ. Wọn yóo fi ìbẹ̀rù wá sọ́dọ̀ OLUWA, wọn yóo sì gba oore rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.

Hosia 3