Hosia 14:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ pada tọ OLUWA Ọlọrun yín lọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ ti kọsẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

2. Ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, kí ẹ sọ pé, “Mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, gba ohun tí ó dára a óo sì máa yìn ọ́ lógo.

3. Asiria kò lè gbà wá là, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gun ẹṣin; a kò sì ní pe oriṣa, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wa, ní Ọlọrun wa mọ́. OLUWA, ìwọ ni ò ń ṣàánú fún ọmọ tí kò lẹ́nìkan.”

Hosia 14