Hosia 1:2-5 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Nígbà tí Ọlọrun kọ́kọ́ bá Israẹli sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosia, Ọlọrun ní, “Lọ fẹ́ obinrin alágbèrè kan, kí o sì bí àwọn ọmọ alágbèrè; nítorí pé àwọn eniyan mi ti ṣe àgbèrè pupọ nípa pé, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀.”

3. Hosia bá lọ fẹ́ iyawo kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gomeri, ọmọ Dibulaimu. Gomeri lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un.

4. OLUWA sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní Jesireeli; nítorí láìpẹ́ yìí ni n óo jẹ ìdílé Jehu níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn tí ó dá ní Jesireeli, n óo sì fi òpin sí ìjọba Israẹli.

5. Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn ọmọ ogun Israẹli ní àfonífojì Jesireeli.”

Hosia 1