Heberu 11:20-26 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Nípa igbagbọ ni Isaaki fi súre fún Jakọbu ati Esau tí ó sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn.

21. Nígbà tí Jakọbu ń kú lọ, nípa igbagbọ ni ó fi súre fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Josẹfu. Ó ń sin Ọlọrun bí ó ti tẹríba lórí ọ̀pá rẹ̀.

22. Nígbà tí ó tó àkókò tí Josẹfu yóo kú, nípa igbagbọ ni ó fi ranti pé àwọn ọmọ Israẹli yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì sọ bí òun ti fẹ́ kí wọ́n ṣe egungun òun.

23. Nígbà tí wọ́n bí Mose, nípa igbagbọ ni àwọn òbí rẹ̀ fi gbé e pamọ́ fún oṣù mẹta nítorí wọ́n rí i pé ọmọ tí ó lẹ́wà ni, wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.

24. Nígbà tí Mose dàgbà tán, nípa igbagbọ ni ó fi kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n pe òun ní ọmọ ọmọbinrin Farao.

25. Ó kúkú yàn láti jìyà pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun jù pé kí ó jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ lọ.

26. Ó ka ẹ̀gàn nítorí Mesaya sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju gbogbo ìṣúra Ijipti lọ, nítorí ó ń wo èrè níwájú.

Heberu 11