1. Ìran tí Ọlọrun fihan wolii Habakuku nìyí.
2. OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí n óo máa ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́; tí o kò sì ní dá mi lóhùn? Tí n óo máa ké pé, “Wo ìwà ipá!” tí o kò sì ní gba olúwarẹ̀ sílẹ̀?
3. Kí ló dé tí o fi ń jẹ́ kí n máa rí àwọn nǹkan tí kò tọ́, tí o jẹ́ kí n máa rí ìyọnu? Ìparun ati ìwà ipá wà níwájú mi, ìjà ati aáwọ̀ sì wà níbi gbogbo.
4. Òfin kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́ òdodo. Àwọn ẹni ibi dòòyì ká olódodo, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ òdodo po.
5. Ọlọrun ní: “Wo ààrin àwọn orílẹ̀-èdè yíká, O óo rí ohun ìjọjú yóo sì yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí mò ń ṣe nǹkan ìyanu kan ní àkókò rẹ, tí o kò ní gbàgbọ́ bí wọ́n bá sọ fún ọ.
6. Wò ó! N óo gbé àwọn ará Kalidea dìde, orílẹ̀-èdè tí ó yára, tí kò sì ní àánú; àwọn tí wọ́n la ìbú ayé já, tí wọn ń gba ilẹ̀ onílẹ̀ káàkiri.
7. Ìrísí wọn bani lẹ́rù; wọ́n ń fi ọlá ńlá wọn ṣe ìdájọ́ bí ó ti wù wọ́n.