Ẹsita 8:15-17 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Modekai jáde ní ààfin ninu aṣọ ọba aláwọ̀ aró ati funfun pẹlu adé wúrà ńlá. Ó wọ aṣọ ìlékè aláwọ̀ elése-àlùkò, ìlú Susa sì ń hó fún ayọ̀.

16. Àwọn Juu sì ní ìmọ́lẹ̀ ati inú dídùn, ayọ̀ ati ọlá.

17. Ní gbogbo agbègbè, ati ní àwọn ìlú tí ìkéde yìí dé, ìdùnnú ati ayọ̀ kún inú àwọn Juu, wọ́n se àsè pẹlu ayẹyẹ, wọ́n sì gba ìsinmi. Àwọn ẹ̀yà mìíràn sọ ara wọn di Juu, nítorí pé ẹ̀rù àwọn Juu ń bà wọ́n.

Ẹsita 8