Ẹsira 8:9-13 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ninu àwọn ọmọ Joabu, Ọbadaya, ọmọ Jehieli, ni olórí;orúkọ igba eniyan ó lé mejidinlogun (218) ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

10. Ninu àwọn ọmọ Bani, Ṣelomiti, ọmọ Josifaya, ni olórí;orúkọ ọgọjọ (160) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

11. Ninu àwọn ọmọ Bebai, Sakaraya, ọmọ Bebai, ni olórí;orúkọ eniyan mejidinlọgbọn ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

12. Ninu àwọn ọmọ Asigadi, Johanani, ọmọ Hakatani, ni olórí;orúkọ aadọfa (110) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

13. Ninu àwọn ọmọ Adonikamu,orúkọ àwọn tí wọ́n dé lẹ́yìn àwọn tí wọ́n kọ́ dé ni:Elifeleti, Jeueli ati Ṣemaaya; orúkọ ọgọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn.

Ẹsira 8