Ẹsira 8:2-9 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ninu àwọn ọmọ Finehasi, Geriṣomu ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Itamari, Daniẹli ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Dafidi,

3. Hatuṣi, ọmọ Ṣekanaya, ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Paroṣi, Sakaraya ni olórí;orúkọ aadọjọ (150) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

4. Ninu àwọn ọmọ Pahati Moabu, Eliehoenai, ọmọ Serahaya, ni olórí;orúkọ igba (200) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

5. Ninu àwọn ọmọ Satu, Ṣekanaya, ọmọ Jahasieli, ni olórí;orúkọ ọọdunrun (300) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

6. Ninu àwọn ọmọ Adini, Ebedi, ọmọ Jonatani, ni olórí;orúkọ aadọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

7. Ninu àwọn ọmọ Elamu, Jeṣaya, ọmọ Atalaya, ni olórí;orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

8. Ninu àwọn ọmọ Ṣefataya, Sebadaya, ọmọ Mikaeli, ni olórí;orúkọ ọgọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

9. Ninu àwọn ọmọ Joabu, Ọbadaya, ọmọ Jehieli, ni olórí;orúkọ igba eniyan ó lé mejidinlogun (218) ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

Ẹsira 8