1. Ní oṣù keje tí àwọn ọmọ Israẹli ti pada sí ìlú wọn, gbogbo wọn péjọ sí Jerusalẹmu.
2. Jeṣua, ọmọ Josadaki pẹlu àwọn alufaa ẹgbẹ́ rẹ̀ ati Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, pẹlu àwọn ìbátan rẹ̀ tún pẹpẹ Ọlọrun Israẹli kọ́, kí wọ́n baà lè máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, eniyan Ọlọrun.