Ẹsira 1:4-6 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ní gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan rẹ̀ ń gbé, kí àwọn aládùúgbò wọn fi fadaka, wúrà, dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn ta wọ́n lọ́rẹ, yàtọ̀ sí ọrẹ àtinúwá fún ilé Ọlọrun.”

5. Àwọn olórí ninu ìdílé ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Bẹnjamini, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi sì dìde, pẹlu àwọn tí Ọlọrun ti fi sí lọ́kàn láti tún ilé OLUWA tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́.

6. Àwọn aládùúgbò wọn fi ohun èlò fadaka ati ti wúrà, ati dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ràn wọ́n lọ́wọ́, yàtọ̀ sí àwọn ọrẹ àtinúwá.

Ẹsira 1