Ẹkún Jeremaya 5:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Wọ́n fi ipá mú àwọn ọdọmọkunrin pé kí wọn máa lọ ọlọ,àwọn ọmọde ru igi títí àárẹ̀ mú wọn!

14. Àwọn àgbààgbà ti sá kúrò ní ẹnubodè;àwọn ọdọmọkunrin sì ti dákẹ́ orin kíkọ.

15. Inú wa kò dùn mọ́;ijó wa ti yipada, ó ti di ọ̀fọ̀.

16. Adé ti ṣíbọ́ lórí wa!A gbé! Nítorí pé a ti dẹ́ṣẹ̀,

17. nítorí náà, ọkàn wa ti rẹ̀wẹ̀sì;ojú wa sì ti di bàìbàì.

18. Nítorí òkè Sioni tí ó di ahoro;tí àwọn ọ̀fàfà sì ń ké lórí rẹ̀.

19. Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ó jọba títí ayé,ìtẹ́ rẹ sì wà láti ìrandíran.

20. Kí ló dé tí o fi gbàgbé wa patapata?Tí o sì kọ̀ wá sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́?

21. Mú wa pada sọ́dọ̀ ara rẹ, OLUWA,kí á lè pada sí ipò wa.Mú àwọn ọjọ́ àtijọ́ wa pada.

22. Ṣé o ti kọ̀ wá sílẹ̀ patapata ni?Àbí o sì tún ń bínú sí wa, inú rẹ kò tíì rọ̀?

Ẹkún Jeremaya 5