Ẹkún Jeremaya 3:43-47 BIBELI MIMỌ (BM)

43. “O gbé ibinu wọ̀ bí ẹ̀wù,ò ń lépa wa,o sì ń pa wá láì ṣàánú wa.

44. O ti fi ìkùukùu bo ara rẹ,tóbẹ́ẹ̀ tí adura kankan kò lè kọjá sọ́dọ̀ rẹ.

45. O ti sọ wá di ààtànati ohun ẹ̀gbin láàrin àwọn eniyan.

46. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ń wẹnu sí wa lára.

47. Ẹ̀rù ati ìṣubú, ìsọdahoro ati ìparun ti dé bá wa.

Ẹkún Jeremaya 3