Ẹkún Jeremaya 1:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ wò ó bí ìlú tí ó kún fún eniyan tẹ́lẹ̀ ti di ahoro,tí ó wá dàbí opó!Ìlú tí ó tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀!Tí ó sì dàbí ọmọ ọba obinrinláàrin àwọn ìlú yòókù.Ó ti wá di ẹni àmúsìn.

2. Ó ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lóru,omijé ń dà lójú rẹ̀,kò sì sí ẹni tí yóo tù ú ninu, láàrin àwọn alajọṣepọ rẹ̀.Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti dà á,wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn,wọ́n sì di ọ̀tá rẹ̀.

3. Juda ti lọ sí ìgbèkùn,wọ́n sì ń fi tipátipá mú un sìn.Nisinsinyii, ó ń gbéààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,kò sì ní ibi ìsinmi.Ọwọ́ àwọn tí wọn ń lépa rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́,ninu ìdààmú rẹ̀.

4. Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Sioni ń ṣe ìdárò,nítorí kò sí ẹni tí ó ń gba ibẹ̀ lọsíbi àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ mọ́.Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti di ahoro,àwọn alufaa rẹ̀ sì ń kẹ́dùn.Wọ́n ń pọ́n àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lójú,òun pàápàá sì ń joró lọpọlọpọ.

5. Àwọn ọ̀tá ilẹ̀ Juda ti borí rẹ̀, wọ́n ti wá di ọ̀gá rẹ̀,nítorí pé, OLUWA ń jẹ ẹ́ níyà fún ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,àwọn ọ̀tá ti ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣáájú,wọ́n ti kó wọn nígbèkùn lọ.

Ẹkún Jeremaya 1