15. Kí ó ranti pé, bí òun OLUWA ti nawọ́ ìyà sí òun ati àwọn eniyan rẹ̀, tí òun sì ti da àjàkálẹ̀ àrùn bò wọ́n; òun ìbá ti pa wọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ ayé,
16. ṣugbọn ìdí pataki tí òun fi jẹ́ kí wọ́n wà láàyè ni láti fi agbára òun hàn Farao, kí wọ́n lè máa ròyìn orúkọ òun OLUWA káàkiri gbogbo ayé.
17. Ó ní Farao sì tún ń gbé ara rẹ̀ ga sí àwọn eniyan òun, kò jẹ́ kí wọ́n lọ.
18. OLUWA ní, “Wò ó, níwòyí ọ̀la, n óo da yìnyín bo ilẹ̀, irú èyí tí kò sí ní ilẹ̀ Ijipti rí, láti ọjọ́ tí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ dó títí di òní yìí.
19. Nítorí náà, yára ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn ẹran rẹ tí wọ́n wà ninu pápá síbi ìpamọ́, nítorí pé yìnyín yóo rọ̀ sórí eniyan ati ẹranko tí ó bá wà ní pápá, tí wọn kò bá kó wọlé, gbogbo wọn ni yóo sì kú.”