Ẹkisodu 4:5-8 BIBELI MIMỌ (BM)

5. OLUWA wí pé, “Èyí yóo mú kí wọ́n gbàgbọ́ pé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu ni ó farahàn ọ́.”

6. OLUWA tún wí fún un pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá. Nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ dẹ́tẹ̀, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

7. Ọlọrun tún ní, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá pada.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá rẹ̀ pada; nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

8. Ọlọrun ní, “Bí wọn kò bá fẹ́ gbà ọ́ gbọ́, tabi bí wọn kò bá náání àmì ti àkọ́kọ́, ó ṣeéṣe kí wọ́n gba àmì keji yìí gbọ́.

Ẹkisodu 4