4. Ó fi idẹ ṣe ayanran ààrò kan fún pẹpẹ náà, ó ṣe é mọ́ abẹ́ ìgbátí rẹ̀, ayanran náà sì bò ó dé agbede meji sí ìsàlẹ̀.
5. Ó da òrùka mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan ayanran idẹ náà, àwọn òrùka wọnyi ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà.
6. Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n.
7. Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà láti máa fi gbé e; pákó ni ó fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, wọ́n sì ní ihò ninu.
8. Ó mu dígí onídẹ, tí àwọn obinrin tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ ń lò, ó fi ṣe agbada idẹ kan, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.