Ẹkisodu 37:7-23 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ó sì fi wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ṣe àwọn Kerubu meji, ó jó wọn mọ́ igun kinni keji ìtẹ́ àánú náà,

8. Kerubu kinni wà ní igun kinni, Kerubu keji sì wà ní igun keji.

9. Àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú náà; wọ́n kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìtẹ́ àánú.

10. Ó fi igi akasia kan tabili kan; gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀.

11. Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀.

12. Ìgbátí tí ó ṣe náà fẹ̀ ní àtẹ́lẹwọ́ kan ati ààbọ̀.

13. Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin tabili náà lábẹ́ ìgbátí rẹ̀,

14. àwọn òrùka yìí ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà.

15. Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá tí wọ́n fi máa ń gbé tabili náà, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n.

16. Wúrà ni ó fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí yóo máa wà lórí tabili náà: àwọn àwo pẹrẹsẹ ati àwọn àwo kòtò fún turari, abọ́, ati ife tí wọn yóo máa fi ta nǹkan sílẹ̀ fún ètùtù.

17. Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá ìgbámú rẹ̀, àṣepọ̀ ni ó ṣe é, pẹlu àwọn fìtílà rẹ̀, ati àwọn kinní kan bí òdòdó tí ó fi dárà sí i lára.

18. Ẹ̀ka mẹfa ni ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà; mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji.

19. Ó ṣe àwọn kinní kan bí òdòdó alimọndi mẹta mẹta sórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà.

20. Ife mẹrin ni ó ṣe sórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí òdòdó alimọndi pẹlu ìrudi ati ìtànná rẹ̀.

21. Ìrudi kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó so mọ́ ara ọ̀pá fìtílà náà lọ́nà mẹtẹẹta.

22. Àṣepọ̀ ni ó ṣe ọ̀pá fìtílà ati ẹ̀ka ara rẹ̀ ati ìrudi abẹ́ wọn; ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe wọ́n.

23. Fìtílà meje ni ó ṣe fún ọ̀pá náà, ojúlówó wúrà ni ó fi ṣe ọ̀pá tí a fi ń pa iná ẹnu fìtílà.

Ẹkisodu 37