37. Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa, ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ọnà aláràbarà sí i lára.
38. Òpó marun-un ni wọ́n ṣe fún àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ṣe ìkọ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n yọ́ wúrà bo àwọn òpó náà, ati àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi gbé àwọn aṣọ títa náà kọ́, ṣugbọn idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn maraarun.