11. “Máa pa àwọn òfin tí mo fún ọ lónìí yìí mọ́. N óo lé àwọn ará Hamori ati àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, jáde kúrò níwájú rẹ.
12. Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ rí i pé ẹ kò bá àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ dá majẹmu kankan, kí wọn má baà dàbí tàkúté tí a dẹ sí ààrin yín.
13. Ṣugbọn, ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn, kí ẹ sì fọ́ gbogbo àwọn ère wọn, kí ẹ sì gé gbogbo igbó oriṣa wọn lulẹ̀.
14. “Ẹ kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, nítorí èmi OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ owú, Ọlọrun tíí máa jowú ni mí.
15. Ẹ kò gbọdọ̀ bá ẹnikẹ́ni dá majẹmu ninu gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà, kí ẹ má baà bá wọn dá majẹmu tán, kí ó wá di pé, nígbà tí wọn bá ń rúbọ sí oriṣa wọn, tí wọn sì ń ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn, wọn óo máa pè yín, pé kí ẹ máa lọ bá wọn jẹ ninu ẹbọ wọn.