4. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́ ìròyìn burúkú náà, ọkàn wọn bàjẹ́, kò sì sí ẹni tí ó fi ohun ọ̀ṣọ́ sí ara rárá.
5. Nítorí náà, OLUWA rán Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé olóríkunkun ni wọ́n, ati pé bí òun bá sọ̀kalẹ̀ sí ààrin wọn ní ìṣẹ́jú kan, òun yóo pa wọ́n run; nítorí náà, kí wọ́n kó gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, kí òun lè mọ ohun tí òun yóo fi wọ́n ṣe.
6. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli bọ́ gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, ní òkè Horebu.
7. Mose a máa pa àgọ́ àjọ sí òkèèrè, lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli, ó sì sọ ọ́ ní àgọ́ àjọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ní ohunkohun láti bèèrè lọ́dọ̀ OLUWA yóo lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà, tí ó wà lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.
8. Nígbàkúùgbà tí Mose bá ń lọ sí ibi àgọ́ àjọ, olukuluku á dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, wọn a sì máa wò ó títí yóo fi wọ inú àgọ́ àjọ lọ.