17. Ọjọ́ náà jẹ́ àmì ayérayé tí ó wà láàrin èmi ati àwọn eniyan Israẹli, pé ọjọ́ mẹfa ni èmi Ọlọrun fi dá ọ̀run ati ayé, ati pé ní ọjọ́ keje, mo dáwọ́ iṣẹ́ ṣíṣe dúró, mo sì sinmi.’ ”
18. Nígbà tí Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀ tán lórí òkè Sinai, ó fún un ní wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí. Ọlọrun fúnra rẹ̀ ni ó fi ìka ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára àwọn wàláà náà.