15. “Igi akasia ni kí o fi ṣe àwọn òpó àgọ́ náà,
16. kí àwọn igi tí yóo dúró ní òòró gùn ní igbọnwọ mẹ́wàá, kí àwọn tí o óo fi dábùú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kọ̀ọ̀kan ààbọ̀.
17. Kí igi kọ̀ọ̀kan ní àtẹ̀bọ̀ meji, tí wọ́n tẹ̀ bọ inú ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe gbogbo àwọn igi tí wọ́n wà ninu àgọ́ náà.
18. Ogún àkànpọ̀ igi ni kí o ṣe sí ìhà gúsù àgọ́ náà.
19. Ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka ni kí o ṣe sí àwọn ogún àkànpọ̀ igi náà, ìtẹ́lẹ̀ meji meji sí àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan, kí ìtẹ́lẹ̀ meji wà fún àtẹ̀bọ̀ igi meji ninu olukuluku àkànpọ̀ igi náà.