Ẹkisodu 23:30-32 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Díẹ̀díẹ̀ ni n óo máa lé wọn jáde fún yín, títí tí ẹ óo fi di pupọ tí ẹ óo sì gba gbogbo ilẹ̀ náà.

31. Ilẹ̀ yín yóo lọ títí kan Òkun Pupa, ati títí lọ kan òkun àwọn ará Filistia, láti aṣálẹ̀ títí lọ kan odò Yufurate, nítorí pé n óo fi àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà le yín lọ́wọ́, ẹ óo sì lé wọn jáde.

32. Ẹ kò gbọdọ̀ bá àwọn tabi àwọn oriṣa wọn dá majẹmu.

Ẹkisodu 23