12. “Bí ẹnikẹ́ni bá lu eniyan pa, pípa ni a óo pa òun náà.
13. Ṣugbọn bí olúwarẹ̀ kò bá mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó jẹ́ pé ó ṣèèṣì ni, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ibìkan tí n óo yàn fún yín.
14. Ṣugbọn bí ẹnìkan bá mọ̀ọ́nmọ̀ bá ẹlòmíràn jà, tí ó sì fi ọgbọ́n àrékérekè pa á, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sálọ sí ibi pẹpẹ mi, fífà ni kí ẹ fà á kúrò níbi pẹpẹ náà kí ẹ sì pa á.
15. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa òun náà.
16. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jí eniyan gbé, kì báà jẹ́ pé ó ti tà á, tabi kí wọ́n ká a mọ́ ọn lọ́wọ́, pípa ni kí wọ́n pa á.
17. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé baba tabi ìyá rẹ̀ ṣépè, pípa ni kí wọ́n pa á.
18. “Bí eniyan meji bá ń jà, tí ọ̀kan bá fi òkúta tabi ẹ̀ṣẹ́ lu ekeji, tí ẹni tí wọ́n lù náà kò bá kú, ṣugbọn tí ó farapa,
19. bí ẹni tí wọ́n lù tí ó farapa náà bá dìde, tí ó sì ń fi ọ̀pá rìn kiri, ẹni tí ó lù ú bọ́ lọ́wọ́ ikú, ṣugbọn dandan ni kí ó san owó fún àkókò tí ẹni tí ó lù náà lò ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, kí ó sì ṣe ètò ìtọ́jú rẹ̀ títí yóo fi sàn.