11. wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Mose pé, “Ṣé kò sí ibojì ní Ijipti ni o fi kó wa kúrò láti wá kú sí ààrin aṣálẹ̀? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí, tí o kó wa kúrò ní Ijipti?
12. Ṣebí a sọ fún ọ ní Ijipti pé kí o fi wá sílẹ̀ kí á máa sin àwọn ará Ijipti tí à ń sìn, nítorí pé kì bá sàn kí á máa sin àwọn ará Ijipti ju kí á wá kú sinu aṣálẹ̀ lọ.”
13. Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn, ó ní, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró gbọningbọnin, kí ẹ wá máa wo ohun tí OLUWA yóo ṣe. Ẹ óo rí i bí yóo ṣe gbà yín là lónìí; nítorí pé àwọn ará Ijipti tí ẹ̀ ń wò yìí, ẹ kò tún ní rí wọn mọ́ laelae.
14. OLUWA yóo jà fún yín, ẹ̀yin ẹ ṣá dúró jẹ́.”
15. OLUWA wí fún Mose pé, “Kí ló dé tí o fi ń ké pè mí, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n tẹ̀síwájú.