1. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ óo la odò Jọdani kọjá sí òdìkejì lónìí, ẹ óo sì gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ. Àwọn ìlú wọn tóbi, tí odi tí wọ́n mọ yí wọn ká sì ga kan ojú ọ̀run.
2. Àwọn eniyan náà pọ̀, wọ́n ṣígbọnlẹ̀. Àwọn òmìrán tíí ṣe ìran Anakimu ni wọ́n. Àwọn tí ẹ ti mọ̀, tí ẹ sì ti ń gbọ́ nípa wọn pé, ‘Ta ni ó lè dúró níwájú àwọn ìran Anaki?’
3. Nítorí náà, kí ẹ mọ̀ lónìí pé, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń lọ níwájú yín, bíi iná ajónirun. Yóo pa wọ́n run, yóo sì tẹ orí wọn ba fun yín, nítorí náà, kíá ni ẹ óo lé wọn jáde, tí ẹ óo sì pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.