3. Ó tẹ orí yín ba, ó jẹ́ kí ebi pa yín, ó fi mana tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí bọ́ yín, kí ẹ lè mọ̀ pé kìí ṣe oúnjẹ nìkan ní o lè mú kí eniyan wà láàyè, àfi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde.
4. Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ yín kò wú, fún odidi ogoji ọdún yìí.
5. Nítorí náà, ẹ mọ̀ ninu ara yín pé, gẹ́gẹ́ bí baba ti máa ń bá ọmọ rẹ̀ wí ni OLUWA ń ba yín wí.
6. Nítorí náà, ẹ pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́, nípa rírìn ní ọ̀nà rẹ̀ ati bíbẹ̀rù rẹ̀.
7. Nítorí pé ilẹ̀ dáradára ni ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín ń mu yín lọ. Ó kún fún ọpọlọpọ adágún omi, ati orísun omi tí ó ń tú jáde ninu àwọn àfonífojì ati lára àwọn òkè.
8. Ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati baali, ọgbà àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́, ati igi pomegiranate, ilẹ̀ tí ó kún fún igi olifi ati oyin.
9. Ilẹ̀ tí ẹ óo ti máa jẹun, tí kò ní sí ọ̀wọ́n oúnjẹ, níbi tí ẹ kò ní ṣe aláìní ohunkohun. Ilẹ̀ tí òkúta rẹ̀ jẹ́ irin, tí ẹ óo sì máa wa idẹ lára àwọn òkè rẹ̀.
10. Nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó, ẹ óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun yín fún ilẹ̀ dáradára tí ó fun yín.
11. “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, nípa àìpa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí,