10. gẹ́gẹ́ bí ẹ ti dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lẹ́bàá òkè Sinai, tí ó fi sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn eniyan náà jọ sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; kí wọ́n sì kọ́ àwọn ọmọ wọn pẹlu.’
11. “Lẹ́yìn náà, ẹ súnmọ́ òkè náà, nígbà tí ó ń jóná, tóbẹ́ẹ̀ tí ahọ́n iná náà fẹ́rẹ̀ kan ojú ọ̀run, tí òkùnkùn ati ìkùukùu bo òkè náà.
12. Ọlọrun ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná náà wá, ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò rí i. Ohùn rẹ̀ nìkan ni ẹ̀ ń gbọ́.
13. Ó sọ majẹmu rẹ̀ fun yín, tíí ṣe àwọn òfin mẹ́wàá tí ó pa láṣẹ fun yín láti tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sí orí tabili òkúta meji.
14. OLUWA pàṣẹ fún mi nígbà náà, láti kọ yín ní ìlànà ati òfin rẹ̀, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà.