Diutaronomi 19:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Èyí wà fún anfaani ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan. Bí ẹnìkan bá ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti ń bá ara wọn ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀, bí ó bá sálọ sí èyíkéyìí ninu àwọn ìlú náà, yóo gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

5. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá lọ sinu igbó pẹlu aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó ti ń fi àáké gé igi lọ́wọ́, bí irin àáké náà bá yọ, tí ó lọ bá aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì pa á; irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú náà, kí ó sì gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

6. Kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹni tí yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ṣèèṣì pa bá ń lé e lọ pẹlu ibinu, bí ibi tí yóo sá àsálà lọ bá jìnnà jù, yóo bá a, yóo sì pa á; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kí wọ́n pa ẹni tí ó ṣèèṣì paniyan yìí, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé òun ati aládùúgbò rẹ̀ kìí ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀.

7. Nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín pé, ẹ níláti ya ìlú mẹta sọ́tọ̀.

8. “Bí OLUWA Ọlọrun yín bá sì mú kí ilẹ̀ yín tóbi síi gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín, tí ó bá fun yín ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún àwọn baba yín,

9. bí ẹ bá lè pa gbogbo òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, nígbà náà, ẹ tún fi ìlú mẹta mìíràn kún àwọn ìlú mẹta ti àkọ́kọ́.

Diutaronomi 19