Diutaronomi 17:17-20 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Kò gbọdọ̀ kó aya jọ kí ọkàn rẹ̀ má baà yipada; bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kó wúrà ati fadaka jọ fún ara rẹ̀.

18. “Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó gba ìwé òfin yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa ọmọ Lefi, kí ó dà á kọ sinu ìwé kan fún ara rẹ̀.

19. Kí ẹ̀dà àwọn òfin yìí máa wà pẹlu rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; kí ó lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun rẹ̀, nípa pípa gbogbo òfin ati ìlànà wọnyi mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn;

20. kí ó má baà rò ninu ara rẹ̀ pé òun ga ju àwọn arakunrin òun lọ, kí ó má baà yipada sí ọ̀tún tabi sí òsì kúrò ninu òfin OLUWA, kí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ lè pẹ́ lórí oyè ní Israẹli.

Diutaronomi 17