Diutaronomi 14:22-26 BIBELI MIMỌ (BM)

22. “Ẹ gbọdọ̀ san ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko yín ní ọdọọdún.

23. Ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun ni kí ẹ ti jẹ ìdámẹ́wàá ọkà yín, ati ti ọtí waini yín, ati ti òróró yín, ati àkọ́bí àwọn mààlúù yín, ati ti agbo ẹran yín; kí ẹ lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín nígbà gbogbo.

24. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá bukun yín tán, tí ibi tí ó yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà jù fun yín láti ru ìdámẹ́wàá ìkórè oko yín lọ,

25. ẹ tà á, kí ẹ sì gba owó rẹ̀ sọ́wọ́, kí ẹ kó owó náà lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.

26. Ẹ fi owó náà ra ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́, ìbáà ṣe akọ mààlúù, tabi aguntan, tabi ọtí waini, tabi ọtí líle, tabi ohunkohun tí ọkàn yín bá ṣá fẹ́. Ẹ óo jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì máa yọ̀, ẹ̀yin ati ìdílé yín.

Diutaronomi 14