5. Ṣugbọn ibi tí OLUWA bá yàn láti gbé ibùjókòó rẹ̀ kà láàrin gbogbo àwọn ẹ̀yà, ibẹ̀ ni kí ẹ máa lọ.
6. Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú gbogbo ẹbọ sísun yín, ati àwọn ẹbọ yòókù wá, ati ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ àtinúwá yín, ati ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA, ati àkọ́bí mààlúù yín, ati ti aguntan yín.
7. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín yóo ti jẹun níwájú OLUWA Ọlọrun yín, inú yín yóo sì dùn nítorí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín tí OLUWA ti fi ibukun sí.
8. “Ẹ kò gbọdọ̀ máa ṣe bí a ti ń ṣe níbí lónìí, tí olukuluku ń ṣe èyí tí ó dára lójú ara rẹ̀.
9. Nítorí pé ẹ kò tíì dé ibi ìsinmi ati ilẹ̀ ìní tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín.
10. Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani, tí ẹ sì ń gbé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, nígbà tí ó bá sì fun yín ní ìsinmi, tí ẹ bá bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó yí yín ká, tí ẹ sì wà ní àìléwu,