30. Òkè Gerisimu ati òkè Ebali wà ní òdìkejì Jọdani, ní ojú ọ̀nà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, ní ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé Araba, ní òdìkejì Giligali, lẹ́bàá igi Oaku More.
31. Nítorí ẹ óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á tán, tí ẹ̀ ń gbé inú rẹ̀,
32. ẹ ṣọ́ra, kí ẹ máa tẹ̀lé gbogbo ìlànà ati òfin tí mo fi lélẹ̀ níwájú yín lónìí.