Daniẹli 8:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Nígbà tí èmi Daniẹli rí ìran náà, bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mọ ìtumọ̀ rẹ̀, ni ẹnìkan bá yọ níwájú mi tí ó dàbí eniyan.

16. Mo gbóhùn ẹnìkan láàrin bèbè kinni keji odò Ulai tí ó wí pé, “Geburẹli, sọ ìtumọ̀ ìran tí ọkunrin yìí rí fún un.”

17. Ó wá sí ẹ̀bá ibi tí mo dúró sí. Bí mo ti rí i, ẹ̀rù bà mí, mo dojúbolẹ̀.Ó bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la ni ohun tí o rí.”

18. Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo sùn lọ fọnfọn, mo dojúbolẹ̀. Ó bá fọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dìde,

19. ó ní, “Ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn ibinu Ọlọrun sí àwọn eniyan lẹ́yìn ọ̀la ni ìran tí o rí.

20. “Àwọn ọba Pasia ati Media ni àgbò tí o rí, tí ó ní ìwo meji lórí.

21. Ìjọba Giriki ni òbúkọ onírun jákujàku tí o rí. Ọba àkọ́kọ́ tí yóo jẹ níbẹ̀ ni ìwo ńlá tí ó wà láàrin ojú rẹ̀.

22. Ìtumọ̀ ìwo tí ó ṣẹ́, tí mẹrin mìíràn sì hù dípò rẹ̀, ni pé lẹ́yìn ikú rẹ̀ ni ìjọba rẹ̀ yóo pín sí mẹrin, ṣugbọn kò ní jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.

23. “Nígbà tí ìjọba wọn bá ń lọ sópin, tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn bá kún ojú ìwọ̀n, ọba kan tí ojú rẹ̀ le, tí ó ní àrékérekè, tí ó sì lágbára yóo gorí oyè.

Daniẹli 8