Daniẹli 7:26-28 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ṣugbọn ìdájọ́ yóo bẹ̀rẹ̀, a óo gba àṣẹ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, a óo sì pa á run patapata.

27. A óo fi ìjọba ati àṣẹ, ati títóbi àwọn ìjọba tí ó wà láyé fún àwọn eniyan mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ, ìjọba ayérayé ni ìjọba wọn yóo jẹ́, gbogbo àwọn aláṣẹ yóo máa sìn ín, wọn yóo sì máa gbọ́ tirẹ̀.’

28. “Òpin ọ̀rọ̀ nípa ìran náà nìyí. Ẹ̀rù èrò ọkàn mi bà mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí ojú mi yipada, ṣugbọn inú ara mi ni mo mọ ọ̀rọ̀ náà sí.”

Daniẹli 7