1. Ní ọdún kinni tí Beṣasari jọba ní Babiloni, Daniẹli lá àlá, o sì rí àwọn ìran kan nígbà tí ó sùn lórí ibùsùn rẹ̀. Ó bá kọ kókó ohun tí ó rí lójú àlá náà sílẹ̀.
2. Ó ní, “Bí mo ti sùn ní alẹ́, mo rí i lójúran pé afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́ láti igun mẹrẹẹrin ayé ń rú omi òkun ńlá sókè.
3. Àwọn ẹranko ńláńlá mẹrin bá jáde láti inú òkun. Ọ̀kan kò jọ̀kan ni àwọn mẹrẹẹrin.
4. Ekinni dàbí kinniun, ó sì ní ìyẹ́ bíi ti idì. Mò ń wò ó títí tí ìyẹ́ rẹ̀ fi fà tu. A gbé e dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji bí eniyan. Ó sì ń ronú bí eniyan.
5. “Ẹranko keji dàbí àmọ̀tẹ́kùn, ó gbé ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan sókè. Ó gbé egungun ìhà mẹta há ẹnu, ó wa eyín mọ́ ọn. Mo sì gbọ́ tí ẹnìkan sọ fún un pé, ‘Dìde, kí o sì máa jẹ ẹran sí i.’