8. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fún gbogbo àwọn iyawo àjèjì tí ó fẹ́, tí wọn ń sun turari, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn oriṣa wọn.
9. Inú bí OLUWA sí Solomoni, nítorí pé, ọkàn rẹ̀ ti yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó fara hàn án nígbà meji,
10. tí ó sì pàṣẹ fún un nítorí ọ̀rọ̀ yìí pé kò gbọdọ̀ bọ oriṣa. Ṣugbọn kò pa òfin OLUWA mọ́.
11. OLUWA bá sọ fún Solomoni pé, “Nítorí pé o ti ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ, o kò pa majẹmu mi mọ́, o kò sì tẹ̀lé ìlànà tí mo pa láṣẹ fún ọ, dájúdájú n óo gba ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, n óo sì fi fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ.
12. Ṣugbọn nítorí ti Dafidi baba rẹ, n kò ní ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí ní àkókò tìrẹ. Ọmọ rẹ ni n óo já ìjọba gbà mọ́ lọ́wọ́.