2. OLUWA bá rán àwọn ọmọ ogun Kalidea, ati ti Siria, ti Moabu, ati ti Amoni, láti pa Juda run bí ọ̀rọ̀ ti OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀.
3. Ìjìyà yìí dé bá Juda láti ọ̀dọ̀ OLUWA, láti pa wọ́n run kúrò níwájú rẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Manase ọba,
4. ati nítorí ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀, nítorí tí ó ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní gbogbo ìgboro Jerusalẹmu, OLUWA kò ní dáríjì í.
5. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoiakimu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.