Àwọn Ọba Keji 22:18-20 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ṣugbọn níti ọba Juda tí ó sọ pé kí ẹ lọ wádìí lọ́wọ́ OLUWA, ẹ sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Nípa ọ̀rọ̀ tí ó ti gbọ́, nítorí pé ó ronupiwada,

19. ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú OLUWA, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó sì sun ẹkún nígbà tí ó gbọ́ ìlérí ìjìyà tí mo ṣe nípa Jerusalẹmu ati àwọn eniyan ibẹ̀, pé n óo sọ Jerusalẹmu di ahoro ati ibi tí àwọn eniyan yóo máa lo orúkọ rẹ̀ láti gégùn-ún. Ṣugbọn mo ti gbọ́ adura rẹ̀ nítorí pé ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọkún níwájú mi.

20. Nítorí náà, n kò ní fi ìyà jẹ Jerusalẹmu nígbà tí ó wà láàyè, n óo jẹ́ kí ó kú ní alaafia.” ’ ”Àwọn ọkunrin náà sì lọ jíṣẹ́ fún Josaya ọba.

Àwọn Ọba Keji 22