Àwọn Ọba Keji 20:18-21 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Wọn yóo kó ninu àwọn ọmọ rẹ lọ fi ṣe ìwẹ̀fà ní ààfin ọba Babiloni.’ ”

19. Hesekaya sọ fún Aisaya pé, “Ọ̀rọ̀ OLUWA tí o sọ dára.” Nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, alaafia ati ìfọ̀kànbalẹ̀ yóo sá wà ní àkókò tòun.

20. Gbogbo nǹkan yòókù tí Hesekaya ṣe, ìwà akọni rẹ̀ ati bí ó ti ṣe adágún omi ati ọ̀nà omi wọ inú ìlú ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

21. Hesekaya kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀; Manase ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Àwọn Ọba Keji 20